Bo tilẹ jẹ pe lati bi ọjọ meloo kan sẹyin ni awọn ọrọ kan ti n jẹ jade lori bi Olu tiluu Itori, Ọba Abdulfatai Akamọ, ṣe kunlẹ niwaju Gomina Dapọ Abiọdun, nibi ayẹyẹ kan to waye
Ṣugbọn ni bayii, Kabiyesi ti tan imọlẹ si ọrọ naa, o ni oloore oun toun ko le tẹju ẹ mọlẹ ni Dapọ Abiọdun, nitori oun to mu wahala ba agbegbe oun lati bi ọdun meloo sẹyin, ni Gomina naa fẹẹ yanju fawọn.
Olu Itori ṣalaye siwaju pe, " Emi kọ ni mo sọ pe mo ni iroyin ayọ fun Gomina,nibi ti mo jokoo si lo ti sọ fun mi pe ki wọn pe mi, oun ni iroyin ayọ fun mi,nibi to jokoo si aye awọn gomina ni, ko si tọna fun mi lati jokoo sibẹ.
"Mo si ni lati bẹrẹ mọlẹ lati gbọ nnkan to n sọ nitori ariwo waa nibẹ.Igba ti wọn si maa sọrọ, wọn lawọn niroyin ayọ fun mi pe ọna marosẹ atijọ, wọn maa bẹrẹ ẹ laarin ọsẹ mẹta si akoko yii.
"Ati pe ọsibitu jẹnẹra to ti fẹẹ wo tan awọn yoo kọ, inu mi dun gan an ni ohun to ba si wu ẹlẹnu ni ko maa sọ, gbogbo eeyan lo ni anfaani lati sọ nnkan to ba wuu"
"Ṣe ko to ọpẹ, gbogbo awọn to n gba oju ọna marosẹ agbegbe mi kọja ni wọn mọ pe ko dara rara, to si kọja sisọ, o si tipẹ taa ti n bẹbẹ fun atunṣe mo wa ri Gomina to fẹẹ ba mi ṣe, ẹ waa ni ki n ma ra baaba niwaju ẹ.
Olu Itori tun ṣapejuwe Gomina Dapọ Abiọdun gẹgẹ bi ẹni to mọ apọnle ọba, ti ko si fọrọ wọn ṣere. O waa ni oun ko kabamọ rara nitori oloore oun ni.
O waa pari ọrọ e pe ka ni akoko toun ba gomina sọrọ, oun duro,gomina jokoo, ọtọ ni ariwo ti wọn yoo ma pa. O ni oun ko ri tawọn to n sọ isọkusọ naa ro, bi ko ṣe bi ilu Itori yoo ṣe tẹsiwaju.